إعدادات العرض
Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba…
Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba se bẹẹ dájúdájú ala náà kòní kó ìnira ba a
Lati ọdọ Abu Qatada - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ pé: Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba se bẹẹ dájúdájú ala náà kòní kó ìnira ba a".
الترجمة
العربية বাংলা English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tiếng Việt සිංහල ئۇيغۇرچە Kurdî Kiswahili Português தமிழ் Nederlands অসমীয়া ગુજરાતી پښتو Hausa മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు Bosanski Македонски Svenska ಕನ್ನಡ Moore Română Українська ไทย मराठी ਪੰਜਾਬੀ دری አማርኛ Wolof ភាសាខ្មែរ Malagasyالشرح
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pé ala daada ti o dun ni ninu láti ojú orun lati ọdọ Ọlọhun ni ti nwa, bẹẹ ni alakala ti ko da ti o si nbani nínú jẹ, lati ọdọ èṣù ni ti nwa. Ẹni k'ẹni ti o bá lala ri nkan ti kò wu u, ki o ya tutọ sí apá òsì rẹ, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburu ala naa, ala náà ko nii ko aburú ba nitoripe Ọlọhun ti fi gbolohun ti o sọ yẹn se okunfa àkóyọ nibi nkan ti kò fẹ ti o le t'ara ala tí o la ṣẹlẹ.فوائد الحديث
Ala ni ohun ti eni t'osun ri loju orun rẹ, ṣugbọn o wọ pọ ki wọn lo gbólóhùn (Arruyah) fún daada ti eni náà ri àti nkan rere, bẹẹni o wọ pọ ki wọn lo gbólóhùn (Al-hulum) fún aburú ati awọn nkan ti ko da ti ẹni náà ba ri, wọn si ma nlo mejeeji sí ààyè ara wọn.
Ipin àlá: 1. Ala daada, ohun ni ala òtítọ àti iro ìdùnnú lati ọdọ Ọlọhun wa, ẹni tó sún aa ri fún raa rẹ tabi ki wọn la ala náà si, 2. Ọrọ ti ẹmi ba araarẹ sọ, ohun naa ni ọrọ ti eniyan ba araarẹ sọ ni feteete, 3. Ibani ninujẹ ati idẹrubani esu (satani) ati awọn idunkoko lati ọdọ rẹ ki o le ba ọmọ anabi Adamọ ninujẹ
Nkan mẹta ti o jẹ abayori nkan ti wọn sọ nipa ala daada: ki o fi ẹyin fún Ọlọhun fún ala náà, ki o si funni ni iro idunu nipa rẹ, ki o si sọ ọ jade, sugbọn ki o sọ ọ fún ẹni tí nfẹran rẹ nikan, ki o ma se sọ ọ fún ẹniti ko fẹran rẹ.
Nkan máàrún ni àkòrí nkán ti wọn ṣọ nipa ẹkọ tó wà fún ala burúkú: ki ẹni naa wa isora pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ati nibi aburú èṣù (satani), ki o si tutọ alátẹgun sí apá òsì rẹ ni ẹẹmẹta ti o ba ti ji, kò si gbọdọ sọ fún ẹnikankan rárá, ti o ba ti fẹ sùn padà ki o yi ẹgbẹ ti o fi sun siwaju pada, ti o ba se eleyi ala náà kò ní ko ìnira ba.
التصنيفات
Awọn ẹkọ ala