Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe irọpo owo fún ẹni tí n nawo rẹ,…

Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe irọpo owo fún ẹni tí n nawo rẹ, bẹẹ ni ikeji yóò máa ṣọ pe: "Bami fi iparun ati ibajẹ sinu owo ẹni tí ó kọ̀ lati ma na owo, tí ó wowọ́ mọ́n owo kankan

Lati ọdọ Abu Hurayrah, kí Ọlọhun bá wa yọnu si, o sọ pe: dájúdájú Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba - sọ bayi pe: Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe irọpo owo fún ẹni tí n nawo rẹ, bẹẹ ni ikeji yóò máa ṣọ pe: "Bami fi iparun ati ibajẹ sinu owo ẹni tí ó kọ̀ lati ma na owo, tí ó wowọ́ mọ́n owo kankan.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti fún wa ni iro pe kosi ọjọ kan ti oorun yọ ayaafi ki awọn malaika meji sọkale ti wọn yóò sì máa pe Ọlọhun, ọkan ninu wọn yóò sọ pé: "Ọlọhun bami fi ọpọ rọpo fún ẹni tí n nawo rẹ ni itẹle aṣẹ Ọlọhun, ati fún awọn ẹbi (ọmọ, iyawo, baba, ati iya....) ati igbalejo, ati sí bi awọn iṣẹ àṣegbọrẹ, bami fi èyí to lóore pupọ ju èyí to na lọ rọpo fun un, ki o si ṣe ibukún Rẹ fun". Ẹnikeji awọn malaika náà yóò máa sọ pe: "Ọlọhun bá mi ṣe iparẹ ati ibajẹ sí owo ẹni tí ó kọ̀ lati maa na owo rẹ, bá mi ko iparun ba owo tabi dukia tí ó kọ̀ lati na fún awọn ti o lẹtọọ sí i".

فوائد الحديث

Lilẹtọọ ṣiṣe adua fún ọlọrẹ fún alekun idapada, ati pe ki wọn fi eyi tó lòóre ju èyí tí o na parọ fun, bẹẹni lilẹtọọ ṣiṣepe le ahun fún iparẹ dukiya rẹ ti o fí nṣe ahun, ti o si kọ̀ lati na a síbi nkan ti Ọlọhun (Allah) ṣe ni ọranyan.

Adua awọn malaika fún àwọn olugbagbọ ododo ti wọn jẹ ẹniire ti wọn na owo pẹlu daada ati ibukun, ati pe adua wọn koni sa láì gba.

Siseni lojuloyin nipa ninawo sibi nkan ti o jẹ dandan ati awọn àṣegbọrẹ; gẹgẹbi ninawo fun awọn araale, ati dida ẹbipo, ati awọn ojupọna daada.

Alaye ọlá ti nbẹ fún ẹni tí n nawo rẹ sí awọn ojupọna oloore, ati pe igbẹyin rẹ nipe Ọlọhun yóò fi imi rọpo fun un, Allah (Ọlọhun) ti ọla Rẹ ga jùlọ sọ pe: (ohunkohun ti ẹ bá ná Ọlọhun ni yóò fi imi rọpo, Oun naa ni O lóore jùlọ ní Olupese fún ni) [sabai: 39].

Eleyi ni iṣẹ epe fún ẹni tí kò ṣe inawo ti o pan dandan fún un, sugbọn awọn inawo ti kii se dandan (eyi ti a fe), ohun kò sí ni bẹ; nitoripe ẹni tí kò ṣe inawo ti kii se dandan kò lẹ tọọ sí epe yii.

Ṣíṣe ahun ati k'okogun (ahun dé orí emi araa ẹni) ni èèwọ̀.

التصنيفات

Saara aṣegbọrẹ