إعدادات العرض
Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi
Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi
Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pé: Allah Ọlọhun ti O gbọngbọn ti O ga jùlọ sọ pé: Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi , ti o ba rántí mi ninu ẹmi rẹ Emi naa yóò rántí rẹ ninu ẹmi Mi, ti o ba rántí mi làárìn awọn ìjọ Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn ti wọn lóore jù ìjọ tiẹ lọ, ti o bá sun mọ mi ni iwọn àlàfo ni na ọmọnika tán Emi yóò sún mọ ni iwọn ni na igunpá, ti o bá sun mọ Mi ni iwọn gigun apá Emi yóò sún mọ ni iwọn gigun ni na apa méjèejì lẹẹkan naa, ti o bá wá bá mi ni eniti nrin, Emi yóò wá bá ní Ẹni ti nyara.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Bahasa Indonesia Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Français Tiếng Việt සිංහල Hausa Kurdî Kiswahili Português தமிழ் Русский Nederlands অসমীয়া ગુજરાતી پښتو മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు मराठी Македонски Svenska Moore Română Українська ไทย ਪੰਜਾਬੀ دری አማርኛ Wolof ភាសាខ្មែរ ಕನ್ನಡ Malagasyالشرح
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) fún wa niro pe dájúdájú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pé: Emi wà pẹlu aba ẹru mi sí mi, Emi yóò sì máa bá a lo nibamu aba rẹ sí mi, pẹlu ini ireti ati ifun ni ni ireti amojukuro, bẹẹni ma máa ṣe oore eyi ti nfọkan sí lọdọ mi, tabi awọn nkan mii; mo wà pẹlu rẹ pẹlu ikẹ ati ifini se kongẹ daada ati itọsọna ati amojuto ati ikun lọwọ nigbati o ba rántí mi. Ti o bá seranti mi ninu ọkan rẹ ni òun nìkan ti ẹnikankan kò si ni bẹ pẹlu sise afọmọ ati gbólóhùn pe kò sí Ọlọhun míràn to yẹ kaa maa sìn àyàafi Allah, tabi awọn ìrántí mii, maa rántí rẹ ninu ẹmi Mi. Ti o bá rántí Mi láàrin àwọn akojọ kan, Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn akojọ ti wọn pọ ti wọn si dáa jù wọn lọ. Ẹni tí o ba sun mọ Ọlọhun ni iwọn ina ika ọwọ mararun tan Ọlọrun yóò se alekun fun yóò wá sun mọ ni iwọn igunpa kan. Ti o bá sun mọ ni iwọn igunpa kan Ọlọhun yóò sún mọ ni iwọn ina apá mejeeji tan lẹ kan naa. Ti o ba wa bá Ọlọhun ni ẹnití nrin Ọlọhun yóò wá ba ni yara yara. Ti ẹru (eniyan) bá sun mọ Oluwa rẹ pẹlu imáa tẹle àṣẹ Rẹ ti o kọ ju sí daada, dajudaju Ọlọhun Oluwa ti O ga jù lọ yóò se alekun ni isunmọ rẹ pada yóò máa jẹ ẹsan iru nkan to se. Gbogbo igba ti ijẹ ẹru fún Ọlọhun ti olugbagbọ ba ti pé fún Oluwa rẹ náà ni Ọlohun ti Ọ̀la Rẹ ga yóò sún mọ, ọrẹ Ọlohun ati ẹsan Rẹ pọ jù iṣẹ ati wahala ti ẹru se lori rẹ lọ, eyi ti o ṣẹlẹ nipe ẹsan Ọ̀lọhun tẹwọn lori iṣẹ ẹru pẹlu ọna ati iye iṣẹ tó ṣe. Olugbagbọ ododo yóò máa daba daada sí Oluwa rẹ, yóò sì máa ṣiṣẹ daada, yóò sì máa yàrá sise daada, yóò sì máa ṣe alekun iṣẹ tí yóò fi pàdé Ọlọhun.فوائد الحديث
Hadith yìí wa nínú hadith ti Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati Ọlà Rẹ ko máa bá) gbawa lati ọdọ Olùwà rẹ. Òun ni won npe ni Ọrọ to mọ tàbí Ọrọ Ọlọhun, ohun ni hadith to se pe gbólóhùn ati ìtumọ rẹ wá lati ọdọ Ọlohun, Sugbọn koni awon nkan idàṣá lesa Al-Qur'an lára èyí ti o fí yatọ sí ọrọ mii, bi ki ká Al-Qur'an fún ìjọsìn ati iṣe imọra síwaju ki a tò le kàá, ati ifi peni nija ati iko agara bá àwọn eniyan lati mu iru rẹ wá, ati awon nkan mii yatọ sí eleyi.
Al-Aajurriy sọ pe: dajudaju awon ẹni òdodo won a ṣe iroyin Ọlọhun ti o gbángban ti o sí tobi ju pẹlu awon iroyin ti o fí royin ará Rẹ Ọba to gbángban ti o Tobi, ati pẹlu bi Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ola Re máa bà) se royin rẹ, ati bi awon saabé (awon musulumi akọkọ) ki Ọlohun yọnu si won se royin rẹ, eleyi ni ilana awọn oni mimọ ti won tẹlé àlàalẹ Anọbi ti won ko da adadaalẹ. O ti pari. Awon ti won tẹlé Sunna (ilana Anọbi) won a ṣe afirinlẹ awon orukọ ati iroyin bi Ọlọhun se fi rinlẹ fún ará Rẹ, lài yi ìtumọ sí bò mí láì sa láì túmọ rẹ bi ko se yẹ lai fún ìtumọ pe bo se ri ni láì ṣe àfìjọ rẹ pẹlu nkan mi. Won a sì máa le jina sí Ọlọhun iru nkan ti o bá lè jina sí ará Rẹ, won a si gbe ẹnu dakẹ ni bi nkan ti Ọlọhun o fí kan rinlẹ tabi le jina. Ọlọhun ti O ga jù lọ sọ pé: (Kosi nkan kan ti o dàbí Ọlọhun tabi ti o jọ Oun ni Olùgbọ ati Olurina).
Iṣẹ ni lati wa papọ mo idaba dàada pẹlu Ọlohun, Al-Hasanul-Basiriy sọ pé: dájúdájú olugbagbọ òdodo ni a máà daba daada pẹlu Oluwa rẹ, yóò sì ṣe iṣẹ ni dàada, dajudaju poki eniyan (ẹni tí o yápa sí àṣẹ Ọlọhun) a ma da àbá aburú sí Oluwa Rẹ yoo si se iṣẹ ni aburu.
Al-Qurtubiy sọ pé: won sọ pé: ìtumọ "ẹrù Mi dá àbá simi" aba pe máa dá loun nigbati o ba ke pè Mí, ati àbá igba iwa aforijin rẹ nigbati o ba tiwa (sí wọ kuro ni bi ẹsẹ) ati àbá riri aforijin nigbati o ba tọrọ idarijin, àbá ifọwọsi nigbati o ba se ìjọsìn pẹlu awon mọjẹmu rẹ ni éniti ṣe amudani adehun òtítọ Ọlọhun, nitoribẹ ni o fi yẹ fún ọmọ eniyan ki o gbiyanju lati máa ṣe nkan ti o yẹ kose ni eni ti yóò mọ dájú pé Ọlọhun yóò gba yóò sì ṣe aforijin fún, nitoripe O ti ṣe adehun bẹ bẹ sí ni Ọlọhun kìí yẹ adehun rẹ, ti O ba di adisọkan tabi o daba pe Ọlọhun o níí gba, tabi ko le ṣe lanfaani eleyi ni isọ ireti nu ninu ikẹ Ọlọhun, ki a sọ iretinu ni bi ikẹ Ọlọhun o wa ninu awon ẹsẹ nla nla, ẹni tó bá ku lori bayi won yoo pati sára àbá ati ero rẹ gẹgẹ bí o se wá ninu awon apakan ọna hadith ti won dàrúkọ, "ki ẹru Mi daba nkan ti o bá wù nipa Mi", ṣugbọn idaba aforinjin pẹlu itẹpẹlẹ mọ ẹsẹ aimokan ni eleyi je ati igbatanjẹ.
Iseni lójú kòkòrò lati se ọpọlọpọ ìrántí Ọlọhun ninu ọkan rẹ ati pẹlu ahán rẹ lapapọ, ninu ẹmi ati ọkan rẹ ni yóò ti ni ifoya fún Ọlohun ti yóò sì má rántí titobi rẹ ati ẹtọ rẹ yóò sì máa nireti si ọdọ Rẹ, yóò sì máa gbé tobi yóò nifẹ rẹ pẹlu idábá dàada sí yóò sì máa ṣiṣẹ ni mimọ fún, yóò ma wí pẹlu ahán: Mimọ ni fún Ọlohun, gbogbo iyin ati ọpẹ ti Ọlọhun níí ṣe, Kosi nkan mi to le tosí ìjọsìn ayáafi Allah (Ọlọhun), Ọlọhun lo tobi jù lọ, kosi ọgbọn kan tabi agbára kan àyàafi pẹlu aṣẹ Ọlọhun.
Ọmọ baba Jamrah sọ pé: ẹni tí o ba rántí Ọlọhun ni ẹnití nfoya (ti nbẹru) Ọlọhun yóò fi lọkan balẹ .
Gbólóhùn Ashibr ni: Aaye àlàfo ti o wa laarin ika ọmọ Landirin titi dé ika àtànpàkò nigbati a ba ná ọwọ, Adhraa'u ni:
alafo aaye ti o wa laarin eteeti ika aarin titi dé eegun igunpa, Al-Baa'u ni: inantan gigun apá mejeeji eniyan looro ati ibu fifẹ igbaaya, ohun lo jẹ odiwon gigun apá mẹrin.